1 Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú padàṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ líle máa ń ru ìbínú sókè.
2 Ahọ́n ọlọgbọ́n a máa gbé ìmọ̀ jádeṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n ń tú ọ̀rọ̀ ọ òmùgọ̀ jáde.
3 Ojú Olúwa wà níbi gbogbo,Ó ń wo àwọn ẹni búburú àti àwọn ẹni rere.
4 Ahọ́n tí ń mú ìtura wá jẹ́ igi ìyèṣùgbọ́n ahọ́n ẹ̀tàn ń pa ẹ̀mí run.
5 Aláìgbọ́n ọmọ kọ ìbáwí baba rẹ̀ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí jẹ́ ọlọgbọ́n.
6 Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra,ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.