6 Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra,ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.
7 Ètè olódodo ń tan ìmọ̀ kalẹ̀;ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ fún ọkàn aláìgbọ́n.
8 Olúwa kórìíra ìrúbọ àwọn ènìyàn búburúṣùgbọ́n àdúrà olódodo tẹ́ẹ lọ́rùn.
9 Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburúṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.
10 Ẹni tí ó kúrò lójú ọ̀nà yóò rí ìbáwí gan an,ẹni tí ó kórìíra ìbáwí yóò kú.
11 Ikú àti ìparun sí sílẹ̀ níwájú Olúwamélòó mélòó ní nínú ọkàn àwọn ènìyàn.
12 Ẹlẹ́gàn kórìíra ìbáwí:kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ọlọ́gbọ́n.