15 Àyà tí ó máa ń jà dàbíọ̀wààrà òjò ní ọjọ́ tí òjò ń rọ̀;
16 dídá a lẹ́kun dàbí ìgbà tí ènìyàn ń dá afẹ́fẹ́ lẹ́kuntàbí bí ẹni tí ó gbá òróró.
17 Bí irin tí ń pọ́n irin múbẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ń pọ́n ẹlòmíràn mú.
18 Ẹni tí ó tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóò jẹ èṣo rẹ̀ẹni tí ó sì fojú tó ọ̀gá rẹ̀ yóò gba ọlá.
19 Bí omi tí ń ṣe àfihàn ojú, nígbà tí a bá wò óbẹ́ẹ̀ ni ọkàn ènìyàn ń ṣe àfihàn ènìyàn.
20 Kò tẹ́ ikú àti ìparun lọ́rùn ríbẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ojú ènìyàn kò rí ìtẹ́lọ́rùn rí.
21 Iná fún fàdákà iná ìlérú fún wúrà,ṣùgbọ́n a ń dán ènìyàn wò nípa ìyìn tí ó ń gbà.