1 Ní oṣù kẹta tí àwọn eniyan Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ Sinai.
2 Refidimu ni wọ́n ti gbéra wá sí aṣálẹ̀ Sinai. Nígbà tí wọ́n dé aṣálẹ̀ yìí, wọ́n pàgọ́ wọn siwaju òkè Sinai.
3 Mose bá gòkè tọ Ọlọrun lọ.OLUWA pè é láti orí òkè náà, ó ní, “Ohun tí mo fẹ́ kí o sọ fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí,
4 ‘Ṣé ẹ rí ohun tí èmi OLUWA fi ojú àwọn ará Ijipti rí, ati bí mo ti fi ẹ̀yìn pọ̀n yín títí tí mo fi kó yín wá sí ọ̀dọ̀ mi níhìn-ín?