25 “Bí o bá yá ẹnikẹ́ni lówó ninu àwọn eniyan mi, tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ, tí ó ṣe aláìní, má ṣe bí àwọn tí wọn ń fi owó wọn gba èlé, má gba èlé lórí owó tí o yá a.
26 Bí aládùúgbò rẹ bá fi ẹ̀wù rẹ̀ dógò lọ́dọ̀ rẹ, tí o sì gbà á, dá a pada fún un kí oòrùn tó wọ̀;
27 nítorí pé ẹ̀wù yìí ni àwọ̀lékè kan ṣoṣo tí ó ní, òun kan náà sì ni aṣọ ìbora rẹ̀. Àbí aṣọ wo ni ó tún ní tí yóo fi bora sùn? Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí ó bá ké pè mí, n óo dá a lóhùn, nítorí pé aláàánú ni mí.
28 “O kò gbọdọ̀ kẹ́gàn Ọlọrun, o kò sì gbọdọ̀ gbé ìjòyè àwọn eniyan rẹ ṣépè.
29 “O kò gbọdọ̀ jáfara láti mú ninu ọpọlọpọ ọkà rẹ ati ọpọlọpọ ọtí waini rẹ láti fi rúbọ sí mi.“O níláti fún mi ní àkọ́bí rẹ ọkunrin pẹlu.
30 Bákan náà ni àkọ́bí mààlúù rẹ ati ti aguntan rẹ, tí wọ́n bá jẹ́ akọ. Fi wọ́n sílẹ̀ pẹlu ìyá wọn fún ọjọ́ meje, ní ọjọ́ kẹjọ o níláti fi wọ́n rúbọ sí mi.
31 “Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí a yà sọ́tọ̀ fún mi, nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ òkú ẹran tí ẹranko bá pa ninu ìgbẹ́, ajá ni kí ẹ gbé irú ẹran bẹ́ẹ̀ fún.