13 “Máa ṣe akiyesi gbogbo ohun tí mo ti sọ fún ọ, má sì ṣe bọ oriṣa kankan, má tilẹ̀ jẹ́ kí n gbọ́ orúkọ wọn lẹ́nu rẹ.
14 “Ìgbà mẹta ni o níláti máa ṣe àjọ̀dún fún mi ní ọdọọdún.
15 O níláti máa ṣe àjọ̀dún àìwúkàrà; gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún ọ; ọjọ́ meje ni o gbọdọ̀ fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní àkókò tí mo yà sọ́tọ̀ ninu oṣù Abibu, nítorí pé ninu oṣù náà ni o jáde ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹnikẹ́ni kò sì gbọdọ̀ wá sí iwájú mi ní ọwọ́ òfo.
16 “O gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè nígbà tí o bá kórè àkọ́so àwọn ohun tí o gbìn sinu oko rẹ.“Ní òpin ọdún, nígbà tí o bá parí ìkórè gbogbo èso oko rẹ, o gbọdọ̀ ṣe àjọ̀dún ìkórè.
17 Ẹẹmẹta ní ọdọọdún ni gbogbo ọkunrin yín níláti wá siwaju èmi OLUWA Ọlọrun yín.
18 “Nígbà tí o bá fi ohun ẹlẹ́mìí rúbọ sí mi, burẹdi tí o bá fi rúbọ pẹlu rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí kò ní ìwúkàrà ninu, ọ̀rá ẹran tí o bá fi rúbọ sí mi kò sì gbọdọ̀ kù di ọjọ́ keji.
19 “Ohunkohun tí o bá kọ́ kórè ninu oko rẹ, ilé OLUWA Ọlọrun rẹ ni o gbọdọ̀ mú un wá.“O kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi wàrà ìyá rẹ̀.