5 Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹni tí ó kórìíra rẹ, tí ẹrù wó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà mọ́lẹ̀, tí kò lè lọ mọ́, o kò gbọdọ̀ gbójú kúrò kí o fi sílẹ̀ níbẹ̀, o níláti bá a sọ ẹrù náà kalẹ̀.
6 “O kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí talaka po nígbà tí ó bá ní ẹjọ́.
7 O kò gbọdọ̀ fi ẹ̀sùn èké kan ẹnikẹ́ni, o kò sì gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tabi olódodo nítorí pé, èmi, OLUWA kò ní dá eniyan burúkú láre.
8 O kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí pé àbẹ̀tẹ́lẹ̀ a máa fọ́ àwọn aláṣẹ lójú, kì í jẹ́ kí wọn rí ẹ̀tọ́, a sì máa mú kí wọn sọ ẹjọ́ aláre di ẹ̀bi.
9 “O kò gbọdọ̀ pọ́n àlejò lójú, ẹ mọ̀ bí ọkàn àlejò ti rí, nítorí ẹ̀yin pàápàá jẹ́ àlejò rí ní ilẹ̀ Ijipti.
10 “Ọdún mẹfa ni kí o fi máa fúnrúgbìn sórí ilẹ̀ rẹ kí o sì fi máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn inú rẹ̀.
11 Ṣugbọn ní ọdún keje, o gbọdọ̀ fi oko náà sílẹ̀ kí ó sinmi, kí àwọn talaka ninu yín náà lè rí oúnjẹ jẹ, kí àwọn ẹranko sì jẹ ninu èyí tí àwọn talaka bá jẹ kù. Bẹ́ẹ̀ ni o gbọdọ̀ ṣe ọgbà àjàrà rẹ, ati ọgbà olifi rẹ pẹlu.