9 pẹpẹ ẹbọ sísun ati gbogbo ohun èlò tí wọn yóo máa lò pẹlu rẹ̀ ati agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀;
10 ati àwọn ẹ̀wù tí a dárà sí, ẹ̀wù mímọ́ Aaroni alufaa ati ẹ̀wù àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa wọn,
11 ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ patapata ni wọn yóo ṣe bí mo ti pa á láṣẹ.”
12 OLUWA rán Mose, ó ní,
13 “Sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, ‘Ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́, nítorí pé òun ni àmì tí ó wà láàrin èmi pẹlu yín ní ìrandíran yín; kí ẹ lè mọ̀ pé, èmi OLUWA yà yín sọ́tọ̀ fún ara mi.
14 Ẹ máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ nítorí pé ọjọ́ mímọ́ ni fún yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ́ di aláìmọ́, pípa ni kí wọ́n pa á; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ náà, a óo yọ ọ́ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.
15 Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ọjọ́ keje jẹ́ ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀, èyí tí ó jẹ́ mímọ́ fún OLUWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan ní ọjọ́ ìsinmi, pípa ni kí wọ́n pa á.