1 Nígbà kan, àwọn ọba mẹrin kan: Amrafeli, ọba Babiloni, Arioku, ọba Elasari, Kedorilaomeri, ọba Elamu, ati Tidali, ọba Goiimu,
2 gbógun ti Bera, ọba Sodomu, Birisa ọba Gomora, Ṣinabu, ọba Adima, Ṣemeberi, ọba Seboimu ati ọba ìlú Bela (tí ó tún ń jẹ́, Soari).
3 Gbogbo wọn pa àwọn ọmọ ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu (tí ó tún ń jẹ́ òkun iyọ̀).
4 Fún ọdún mejila gbáko ni àwọn ọba maraarun yìí fi sin Kedorilaomeri, ṣugbọn ní ọdún kẹtala, wọ́n dìtẹ̀.
5 Ní ọdún kẹrinla, Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀ wá, wọ́n ṣẹgun Refaimu tí ó wà ní Aṣiterotu Kanaimu. Bákan náà, wọ́n ṣẹgun àwọn Susimu tí wọ́n wà ní Hamu, àwọn Emimu tí wọ́n wà ní Ṣafe-kiriataimu,