19 Ó súre fún Abramu, ó ní:“Kí Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun Abramu.
20 Ìyìn sì ni fún Ọlọrun Ọ̀gá Ògo,ẹni tí ó bá ọ ṣẹgun àwọn ọ̀tá rẹ.”Abramu bá fún Mẹlikisẹdẹki ní ìdámẹ́wàá gbogbo ìkógun tí ó kó bọ̀.
21 Ọba Sodomu sọ fún Abramu pé, “Jọ̀wọ́, máa kó gbogbo ìkógun lọ, ṣugbọn dá àwọn eniyan mi pada fún mi.”
22 Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn ó ní: “Mo ti búra fún OLUWA Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé,
23 pé, abẹ́rẹ́ lásán, n kò ní fọwọ́ mi kàn ninu ohun tí ó jẹ́ tìrẹ, kí o má baà sọ pé ìwọ ni o sọ mí di ọlọ́rọ̀.
24 N kò ní fọwọ́ mi kan ohunkohun àfi ohun tí àwọn ọmọkunrin tí wọ́n bá mi lọ ti jẹ, ati ìpín tiwọn tí ó kàn wọ́n, ṣugbọn jẹ́ kí Aneri, Eṣikolu ati Mamure kó ìpín tiwọn.”