1 Isaaki bá pe Jakọbu, ó súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani.
2 Ó ní, “Dìde, lọ sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, ní Padani-aramu, kí o sì fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Labani, arakunrin ìyá rẹ.
3 Ọlọrun Olodumare yóo bukun ọ, yóo fún ọ ní ọmọ pupọ, yóo sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.
4 Ìre tí ó sú fún Abrahamu yóo mọ́ ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ lórí. Ilẹ̀ tí ó fún Abrahamu, níbi tí Abrahamu ti jẹ́ àjèjì yóo sì di tìrẹ.”
5 Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki ṣe rán Jakọbu jáde lọ sí Padani-aramu lọ́dọ̀ Labani, ọmọ Betueli, ará Aramea, arakunrin Rebeka, ìyá Jakọbu ati Esau.
6 Esau rí i pé Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán an lọ sí Padani-aramu kí ó lọ fẹ́ iyawo, ati pé nígbà tí ó ń súre fún un, ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani.