12 Nígbà tí ó sùn, ó lá àlá kan, ó rí àkàsọ̀ kan lójú àlá, wọ́n gbé e kalẹ̀, orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run. Ó wá rí i tí àwọn angẹli Ọlọrun ń gùn ún lọ sókè sódò.
13 OLUWA pàápàá dúró lókè rẹ̀, ó wí fún un pé, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun Abrahamu baba rẹ ati Ọlọrun Isaaki, ilẹ̀ tí o dùbúlẹ̀ sí yìí, ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fi fún.
14 Àwọn ọmọ rẹ yóo pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, o óo sì gbilẹ̀ káàkiri sí ìhà ìwọ̀ oòrùn ati sí ìhà ìlà oòrùn, sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù nípasẹ̀ rẹ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo bukun aráyé.
15 Wò ó, mo wà pẹlu rẹ, n óo pa ọ́ mọ́ níbikíbi tí o bá lọ, n óo sì mú ọ pada wá sí ilẹ̀ yìí, nítorí pé n kò ní fi ọ́ sílẹ̀ títí tí n óo fi ṣe gbogbo ohun tí mo sọ fún ọ.”
16 Nígbà tí Jakọbu tají ní ojú oorun rẹ̀, ó ní, “Dájúdájú OLUWA ń bẹ níhìn-ín, n kò sì mọ̀!”
17 Ẹ̀rù bà á, ó sì wí pé, “Ààrin yìí mà tilẹ̀ bani lẹ́rù pupọ o! Ibí yìí kò lè jẹ́ ibòmíràn bíkòṣe ilé Ọlọrun, ibí gan-an ni ẹnu ibodè ọ̀run.”
18 Jakọbu bá dìde ní òwúrọ̀ kutukutu, ó gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí nàró gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀n, ó sì da òróró sórí rẹ̀.