9 Ìtàn ìran Noa nìyí: Noa jẹ́ olódodo, òun nìkan ṣoṣo ni eniyan pípé ní àkókò tirẹ̀, ó sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu OLUWA.
10 Ó bí ọmọkunrin mẹta tí orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti.
11 Ayé kún fún ìwà ìbàjẹ́ lójú Ọlọrun, ìwà jàgídíjàgan sì gba gbogbo ayé.
12 Ọlọrun rí i pé ayé ti bàjẹ́, nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo eniyan ń hù.
13 Ọlọrun bá sọ fún Noa pé, “Mo ti pinnu láti pa gbogbo ẹ̀dá alààyè run, nítorí ìwà ipá wọn ti gba gbogbo ayé, àtàwọn àtayé ni n óo parun.
14 Nítorí náà, fi igi goferi kan ọkọ̀ ojú omi fún ara rẹ. Ṣe ọpọlọpọ yàrá sinu rẹ̀, kí o sì fi ọ̀dà kùn ún ninu ati lóde.
15 Bí o óo ti kan ọkọ̀ náà nìyí: kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọọdunrun (300) igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ.