1 Bẹ̃ni Abijah sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu Dafidi: Asa ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀. Li ọjọ rẹ̀, ilẹ na wà li alafia li ọdun mẹwa.
2 Asa si ṣe eyi ti o dara, ti o si tọ́ li oju Oluwa Ọlọrun rẹ̀.
3 Nitori ti o mu pẹpẹ awọn ajeji oriṣa kuro, ati ibi giga wọnni, o si wó awọn ere palẹ, o si bẹ ere-oriṣa wọn lulẹ:
4 O si paṣẹ fun Juda lati ma wá Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn, ati lati ma pa aṣẹ ati ofin rẹ̀ mọ́.
5 O si mu ibi giga wọnni ati ọwọ̀n-õrun wọnni kuro lati inu gbogbo ilu Juda: ijọba na si wà li alafia niwaju rẹ̀.
6 O si kọ́ ilu olodi wọnni ni Juda, nitoriti ilẹ na ni isimi, on kò si ni ogun li ọdun wọnni; nitori Oluwa ti fun wọn ni isimi.
7 O si sọ fun Juda pe, Ẹ jẹ ki a kọ́ ilu wọnni, ki a si mọdi yi wọn ka, ati ile-iṣọ, ilẹkun ati ọpa-idabu, nigbati ilẹ na si wà niwaju wa, nitori ti awa ti wá Oluwa Ọlọrun wa, awa ti wá a, on si ti fun wa ni isimi yikakiri. Bẹ̃ni nwọn kọ́ wọn, nwọn si ṣe rere.