4 Nigbati Jehoramu si dide si ijọba baba rẹ̀, o mu ara rẹ̀ le, o si fi idà pa gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, ati ninu awọn ijoye Israeli.
5 Jehoramu jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọ̀n nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mẹjọ ni Jerusalemu.
6 O si rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, gẹgẹ bi ile Ahabu ti ṣe: nitoriti o ni ọmọbinrin Ahabu li aya: o si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa.
7 Ṣugbọn Oluwa kò fẹ ipa ile Dafidi run, nitori majẹmu ti o ti ba Dafidi da, ati bi o ti ṣe ileri lati fun u ni imọlẹ kan ati fun awọn ọmọ rẹ̀ lailai.
8 Li ọjọ rẹ̀ li awọn ara Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda, nwọn si jẹ ọba fun ara wọn.
9 Nigbana ni Jehoramu rekọja lọ pẹlu awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo kẹkẹ́ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: o si dide li oru, o si kọlù awọn ara Edomu ti o ká a mọ, ati awọn olori kẹkẹ́.
10 Sibẹ awọn ara Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda, titi di oni yi. Akokò na pẹlu ni Libna ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ rẹ̀; nitoriti o ti kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ.