2. Kro 25:12-18 YCE

12 Ati ẹgbãrun alãye li awọn ọmọ Juda kó ni igbekun lọ, nwọn si mu wọn lọ si òke apata na, nwọn si tãri wọn silẹ lati òke apata na, nwọn si fọ́ tũtu.

13 Ṣugbọn awọn ọmọ-ogun ti Amasiah ran pada lọ, ki nwọn ki o máṣe ba on lọ si ogun, kọlù awọn ilu Juda lati Samaria titi de Bet-horoni, nwọn si pa ẹgbẹdogun ninu wọn, nwọn si kó ikógun pipọ.

14 O si ṣe lẹhin ti Amasiah ti ibi pipa awọn ara Edomu bọ̀, o si mu awọn oriṣa awọn ọmọ Seiri bọ̀, o si gà wọn li oriṣa fun ara rẹ̀, o si tẹ̀ ara rẹ̀ ba niwaju wọn, o si sun turari fun wọn.

15 Nitorina ni ibinu Oluwa ru si Amasiah, o si ran woli kan si i, ti o wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi nwá oriṣa awọn enia na, ti kò le gbà awọn enia wọn lọwọ rẹ?

16 O si ṣe bi o ti mba a sọ̀rọ, ọba si wi fun u pe, A ha fi ọ ṣe igbimọ̀ ọba bi? fi mọ: ẹ̃ṣe ti a o fi pa ọ? Nigbana ni woli na fi mọ; o si wipe, Emi mọ̀ pe, Ọlọrun ti pinnu rẹ̀ lati pa ọ run, nitoriti iwọ ti ṣe eyi, ti iwọ kò si tẹ eti si imọ̀ran mi.

17 Nigbana ni Amasiah, ọba Juda, gbà ẹ̀kọ, o si ranṣẹ si Joaṣi ọmọ Jehoahasi, ọmọ Jehu ọba Israeli, wipe, Wá, jẹ ki a wò ara wa li oju.

18 Joaṣi, ọba Israeli, si ranṣẹ si Amasiah, ọba Judah, wipe, Ẹgun-ọ̀gan ti o wà ni Lebanoni ranṣẹ si igi kedari ti o wà ni Lebanoni, wipe, Fi ọmọbinrin rẹ fun ọmọ mi li aya: ẹranko igbẹ kan ti o wà ni Lebanoni si kọja nibẹ, o si tẹ ẹ̀gun-ọ̀gan na mọlẹ.