5 Amasiah si kó Juda jọ, o si tò wọn lẹsẹsẹ gẹgẹ bi ile baba wọn, awọn balogun ẹgbẹgbẹrun ati balogun ọrọrun, ani gbogbo Juda ati Benjamini, o si ka iye wọn lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̀ lọ, o si ri wọn li ọkẹ mẹdogun enia ti a yàn, ti o le jade lọ si ogun, ti o si le lo ọ̀kọ ati asà.
6 O si bẹ̀ ọkẹ marun ogun alagbara akọni ọkunrin lati inu Israeli wá fun ọgọrun talenti fadakà.
7 Ṣugbọn enia Ọlọrun kan tọ̀ ọ wá, wipe, Ọba, máṣe jẹ ki ogun Israeli ki o ba ọ lọ: nitoriti Oluwa kò wà pẹlu Israeli, ani gbogbo awọn ọmọ Efraimu.
8 Ṣugbọn bi iwọ o ba lọ, ma lọ, mu ara le fun ogun na: Ọlọrun yio bì ọ ṣubu niwaju ọta: Ọlọrun sa li agbara lati ṣe iranlọwọ, ati lati bì ni ṣubu.
9 Amasiah si wi fun enia Ọlọrun na pe, Ṣugbọn kili awa o ha ṣe nitori ọgọrun talenti ti mo ti fi fun ẹgbẹ-ogun Israeli? Enia Ọlọrun na si dahùn pe, O wà li ọwọ Oluwa lati fun ọ li ọ̀pọlọpọ jù eyi lọ.
10 Nigbana li Amasiah yà wọn, ani ẹgbẹ-ogun ti o ti tọ̀ ọ lati Efraimu wá, lati tun pada lọ ile wọn: ibinu wọn si ru gidigidi si Juda, nwọn si pada si ile wọn ni irunu.
11 Amasiah si mu ara le, o si kó awọn enia rẹ̀ jade, o si lọ si afonifoji iyọ̀, o si pa ẹgbarun ninu awọn ọmọ Seiri.