8 Nitorina ibinu Oluwa wà lori Juda ati Jerusalemu, o si fi wọn fun wàhala, ati iyanu ati ẹ̀sin, bi ẹnyin ti fi oju nyin ri.
9 Sa wò o, awọn baba wa ti ti ipa idà ṣubu, ati awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa, ati awọn obinrin wa wà ni igbekun nitori eyi.
10 Njẹ o wà li ọkàn mi lati ba Oluwa Ọlọrun Israeli dá majẹmu, ki ibinu rẹ̀ kikan ki o le yipada kuro lọdọ wa.
11 Ẹnyin ọmọ mi, ẹ máṣe jafara nisisiyi: nitori ti Oluwa ti yàn nyin lati duro niwaju rẹ̀, lati sìn i, ati ki ẹnyin ki o mã ṣe iranṣẹ fun u, ki ẹ si mã sun turari.
12 Nigbana li awọn ọmọ Lefi dide, Mahati, ọmọ Amasai, ati Joeli, ọmọ Asariah, ninu awọn ọmọ Kohati: ati ninu awọn ọmọ Merari, Kiṣi, ọmọ Abdi, ati Asariah, ọmọ Jehaleeli: ati ninu awọn ọmọ Gerṣoni, Joah, ọmọ Simma, ati Edeni, ọmọ Joah:
13 Ati ninu awọn ọmọ Elisafani, Ṣimri ati Jegieli: ati ninu awọn ọmọ Asafu, Sekariah ati Mattaniah.
14 Ati ninu awọn ọmọ Hemani, Jehieli ati Ṣimei: ati ninu awọn ọmọ Jedutuni, Ṣemaiah ati Ussieli.