6 O si yàn awọn balogun lori awọn enia, o si kó wọn jọ pọ̀ sọdọ rẹ̀ ni ita ẹnu-bode ilu, o si sọ̀rọ iyanju fun wọn, wipe,
7 Ẹ mu ara le, ki ẹ si ṣe onigboya, ẹ má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò nyin nitori ọba Assiria, tabi nitori gbogbo ọ̀pọlọpọ enia ti o wà pẹlu rẹ̀; nitori awọn ti o pẹlu wa jù awọn ti o pẹlu rẹ̀ lọ:
8 Apa ẹran-ara li o pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa Ọlọrun wa li o pẹlu wa lati ràn wa lọwọ, ati lati jà ogun wa. Awọn enia na si gbẹkẹ wọn le ọ̀rọ Hesekiah, ọba Juda.
9 Lẹhin eyi ni Sennakeribu, ọba Assiria, rán awọn iranṣẹ si Jerusalemu, (ṣugbọn on tikararẹ̀ dótì Lakiṣi ati gbogbo ogun rẹ̀ pẹlu rẹ̀) sọdọ Hesekiah, ọba Juda ati sọdọ gbogbo Juda ti o wà ni Jerusalemu wipe,
10 Bayi ni Sennakeribu, ọba Assiria, wi pe, Kili ẹnyin gbẹkẹle, ti ẹnyin joko ninu odi agbara ni Jerusalemu?
11 Kò ṣepe Hesekiah ntàn nyin lati fi ara nyin fun ikú, nipa ìyan, ati nipa ongbẹ, o nwipe, Oluwa, Ọlọrun wa, yio gbà wa lọwọ ọba Assiria?
12 Kò ṣepe Hesekiah kanna li o mu ibi giga rẹ̀ wọnni kuro, ati pẹpẹ rẹ̀, ti o si paṣẹ fun Juda ati Jerusalemu, wipe, Ki ẹnyin ki o mã sìn niwaju pẹpẹ kan, ki ẹnyin ki o mã sun turari lori rẹ̀?