10 Awọn wọnyi li olori awọn alaṣẹ Solomoni ọba, adọtalerugba ti nṣakoso lori awọn enia.
11 Solomoni si mu ọmọbinrin Farao gòke lati ilu Dafidi wá si ile ti o kọ́ fun u; nitori ti o wipe, Ni temi, obinrin kan kì yio gbe inu ile Dafidi, ọba Israeli, nitori mimọ́ ni ibi ti apoti-ẹri Oluwa ti de.
12 Nigbana ni Solomoni ru ẹbọ ọrẹ-sisun si Oluwa lori pẹpẹ Oluwa, ti o ti tẹ niwaju iloro na.
13 Ani nipa ilana ojojumọ, lati ma rubọ gẹgẹ bi aṣẹ Mose, li ọjọjọ isimi, ati li oṣoṣu titun, ati ajọ mimọ́, lẹ̃mẹta li ọdun, ani li ajọ aiwukara, li ajọ ọsẹ-meje, ati li ajọ ipagọ.
14 O si yàn ipa awọn alufa, gẹgẹ bi ilana Dafidi baba rẹ̀, si ìsin wọn, ati awọn ọmọ Lefi si iṣẹ wọn, lati ma yìn, ati lati ma ṣe iranṣẹ niwaju awọn alufa, bi ilana ojojumọ: ati awọn adèna pẹlu ni ipa ti wọn li olukuluku ẹnu-ọ̀na: nitori bẹ̃ni Dafidi, enia Ọlọrun, ti pa a li aṣẹ.
15 Nwọn kò si yà kuro ninu ilana ọba nipa ti awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi niti olukuluku ọ̀ran, ati niti iṣura.
16 Gbogbo iṣẹ Solomoni li a ti pese silẹ bayi de ọjọ ifi-ipilẹ ile Oluwa le ilẹ titi o fi pari. A si pari ile Oluwa.