1 Sámúẹ́lì 27:5-11 BMY

5 Dáfídì sì wí fún Ákíṣì pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí; èmi yóò máa gbé ibẹ̀: èéṣé tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba.”

6 Ákíṣì sí fi Síkílágì fún un ní ijọ́ náà nítorí náà ni Síkílágì fí dí ọba Júdà títí ó fí dì òní yìí.

7 Iye ọjọ́ tí Dáfídì fi jókòó ní ìlú àwọn Fílístínì sì jẹ́ ọdún kan àti oṣù mẹ́rin

8 Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Gésúrì, àti àwọn ara Gésírà, àti àwọn ará Ámálékì àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣúrì títí ó fí dé ilẹ̀ Éjíbítì.

9 Dáfídì sì kọlu ilẹ̀ náà kò sì fi ọkùnrin tàbí obìnrin sílẹ̀ láàyè, ó sì kó àgùntàn, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ràkúnmí, àti aṣọ, ó sì yípadà ó tọ Ákíṣì wá.

10 Ákíṣì sì bi í pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé rìn sí lónìí?” Dáfídì sì dáhùn pé, “Síhà gúsù ti Júdà ni, tàbí Síhà gúsù ti Jérámélì,” tàbí “Síhà gúsù ti àwọn ará Kénì.”

11 Dáfídì kò sì dá ọkùnrin tàbí obìnrin sí láàyè, láti mú ìròyìn wá sí Gátì, wí pé, “Ki wọn máa bá à sọ ọ̀rọ̀ wa nibẹ̀, pé, ‘Báyìí ni Dáfídì ṣe’ ” Àti bẹ́ẹ̀ ni iṣe rẹ̀ yóò sì rí ni gbogbo ọjọ́ ti yóò fí jókòó ni ìlú àwọn Fílístínì.