24 Ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín, ẹ gbọdọ̀ máa pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin títí lae.
25 Nígbà tí ẹ bá sì dé ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ìsìn yìí.
26 Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá sì bi yín léèrè pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ìsìn yìí?’
27 ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá OLUWA ni, nítorí pé ó ré ilé àwọn eniyan Israẹli kọjá ní Ijipti, nígbà tí ó ń pa àwọn ará Ijipti, ṣugbọn ó dá àwọn ilé wa sí.’ ” Àwọn eniyan Israẹli wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA.
28 Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose ati Aaroni.
29 Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, OLUWA lu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti pa, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí àrẹ̀mọ ọba Farao tí ó wà lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí ẹrú tí ó wà ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn.
30 Farao bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, òun ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Ijipti. Igbe ẹkún ńlá sì sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé kò sí ẹyọ ilé kan tí eniyan kò ti kú.