10 Joṣua ṣe bí Mose ti pàṣẹ fún un, ó bá àwọn ará Amaleki jagun. Mose ati Aaroni ati Huri bá gun orí òkè lọ.
11 Nígbà tí Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, àwọn ọmọ Israẹli a máa borí àwọn ará Amaleki, nígbà tí ó bá sì rẹ ọwọ́ sílẹ̀, àwọn ará Amaleki a máa borí àwọn ọmọ Israẹli.
12 Nígbà tí ó yá, apá bẹ̀rẹ̀ sí ro Mose, wọ́n gbé òkúta kan fún un láti fi jókòó, ó sì jókòó lórí rẹ̀. Aaroni ati Huri bá a gbé apá rẹ̀ sókè, ẹnìkan gbé apá ọ̀tún, ẹnìkejì sì gbé apá òsì. Apá rẹ̀ wà lókè títí tí oòrùn fi ń lọ wọ̀.
13 Joṣua bá fi idà pa Amaleki ati àwọn eniyan rẹ̀ ní ìpakúpa.
14 OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sinu ìwé kan fún ìrántí, sì kà á sí etígbọ̀ọ́ Joṣua, pé n óo pa Amaleki rẹ́ patapata, a kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́ láyé.”
15 Mose bá tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni àsíá mi.”
16 Ó ní, “Gbé àsíá OLUWA sókè! OLUWA yóo máa bá ìrandíran àwọn ará Amaleki jà títí lae.”