Ẹkisodu 22:8-14 BM

8 Bí ọwọ́ kò bá wá tẹ olè, ẹni tí ó gba ìṣúra pamọ́ yìí gbọdọ̀ wá sí ilé Ọlọrun kí ó fi Ọlọrun ṣẹ̀rí pé òun kò fi ọwọ́ kan ìṣúra tí aládùúgbò òun fi pamọ́ sí òun lọ́wọ́.

9 “Nígbàkúùgbà tí ohun ìní bá di àríyànjiyàn láàrin eniyan meji, kì báà jẹ́ mààlúù, tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tabi aguntan, tabi aṣọ, tabi ohunkohun tí ó bá ti sọnù, tí ó sì di àríyànjiyàn, àwọn mejeeji tí wọn ń lọ́ nǹkan mọ́ ara wọn lọ́wọ́ gbọdọ̀ wá sí ilé Ọlọrun, kí wọ́n sì fi Ọlọrun ṣẹ̀rí, ẹni tí Ọlọrun bá dá lẹ́bi yóo san ìlọ́po meji nǹkan náà fún ẹnìkejì rẹ̀.

10 “Bí ẹnìkan bá fún aládùúgbò rẹ̀ ní ẹran sìn, kì báà ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù, tabi aguntan, bí ẹran náà bá kú tabi kí ó farapa, tabi tí ó bá rìn lọ tí kò sì sí ẹni tí ó rí i,

11 aládùúgbò náà yóo lọ sí ilé Ọlọrun, yóo sì fi OLUWA ṣẹ̀rí pé òun kọ́ ni òun jí ẹran tí wọn fún òun sìn. Ẹni tí ó fún un ní ẹran sìn yóo faramọ́ ìbúra yìí, kò sì ní gbẹ̀san mọ́.

12 Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé wọ́n jí i gbé mọ́ ọn lọ́wọ́ ni, yóo san ẹ̀san fún ẹni tí ó ni ín.

13 Bí ó bá jẹ́ pé ẹranko burúkú ni ó pa á, bí ó bá ní ohun tí ó lè fi ṣe ẹ̀rí, tí ó sì fi ohun náà han ẹni tí ó ni ẹran náà, kò ní san ẹ̀san ẹran náà pada.

14 “Bí ẹnìkan bá yá ẹran ọ̀sìn kẹ́ran ọ̀sìn lọ́wọ́ aládùúgbò rẹ̀, tí ẹran náà bá farapa tabi tí ó kú, tí kò sì sí olówó ẹran náà níbẹ̀, ẹni tí ó yá ẹran náà níláti san án pada.