18 Gígùn àgbàlá náà yóo jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ marun-un pẹlu aṣọ títa tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe ati ìtẹ́lẹ̀ idẹ.
19 Idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò inú àgọ́ náà ati gbogbo èèkàn rẹ̀, ati gbogbo èèkàn àgbàlá náà.
20 “Pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli pé kí wọn mú ojúlówó òróró olifi wá fún títan iná, kí wọ́n lè gbé fìtílà kan kalẹ̀ tí yóo máa wà ní títàn nígbà gbogbo.
21 Yóo wà ninu àgọ́ àjọ, lọ́wọ́ ìta aṣọ títa tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa tọ́jú rẹ̀ níwájú OLUWA láti àṣáálẹ́ títí di òwúrọ̀. Kí àwọn eniyan Israẹli sì máa pa ìlànà náà mọ́ títí lae, láti ìrandíran.