8 mo sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti wá gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati láti kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dára, tí ó sì tẹ́jú, ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin, àní, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Hifi ati ti àwọn ará Jebusi.
9 Igbe àwọn eniyan Israẹli ti gòkè tọ̀ mí wá, mo sì ti rí bí àwọn ará Ijipti ṣe ń ni wọ́n lára.
10 Wá, n óo rán ọ sí Farao, kí o lè lọ kó àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.”
11 Ṣugbọn Mose dá Ọlọrun lóhùn pé, “Ta ni mo jẹ́, tí n óo fi wá tọ Farao lọ pé mo fẹ́ kó àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti?”
12 Ọlọrun bá dá a lóhùn pé, “N óo wà pẹlu rẹ, ohun tí yóo sì jẹ́ àmì fún ọ, pé èmi ni mo rán ọ ni pé, nígbà tí o bá ti kó àwọn eniyan náà kúrò ní Ijipti, ẹ óo sin Ọlọrun ní orí òkè yìí.”
13 Mose tún bi Ọlọrun pé, “Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli, tí mo sì wí fún wọn pé, ‘Ọlọrun àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ bí wọ́n bá wá bi mí pé ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni kí n wí fún wọn?”
14 Ọlọrun dá Mose lóhùn pé, “ÈMI NI ẸNI TÍ MO JẸ́. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘ÈMI NI ni ó rán mi sí yín.’ ”