1 OLUWA tún pe Mose, ó ní, “Dìde kúrò níhìn-ín, ìwọ ati àwọn eniyan tí o kó wá láti ilẹ̀ Ijipti, ẹ lọ sí ilẹ̀ tí mo ti búra fún Abrahamu, ati fún Isaaki, ati fún Jakọbu pé n óo fún arọmọdọmọ wọn.
2 N óo rán angẹli mi ṣáájú yín, n óo sì lé àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hamori, àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi jáde.
3 Ẹ lọ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá náà, tí ó kún fún wàrà ati oyin; n kò ní sí ní ààrin yín nígbà tí ẹ bá ń lọ, nítorí orí kunkun yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ n óo pa yín run lójú ọ̀nà.”
4 Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́ ìròyìn burúkú náà, ọkàn wọn bàjẹ́, kò sì sí ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ sí ara rárá.
5 Nítorí náà, OLUWA rán Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé olóríkunkun ni wọ́n, ati pé bí òun bá sọ̀kalẹ̀ sí ààrin wọn ní ìṣẹ́jú kan, òun yóo pa wọ́n run; nítorí náà, kí wọ́n kó gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, kí òun lè mọ ohun tí òun yóo fi wọ́n ṣe.
6 Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli bọ́ gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò, ní òkè Horebu.