6 Mose bá pàṣẹ, wọ́n sì kéde yí gbogbo àgọ́ ká, pé kí ẹnikẹ́ni, kì báà ṣe ọkunrin, tabi obinrin, má wulẹ̀ ṣòpò láti mú ọrẹ wá fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà mọ́. Wọ́n sì dá àwọn eniyan náà lẹ́kun pé kí wọ́n má mú ọrẹ wá mọ́;
7 nítorí pé ohun tí wọ́n ti mú wá ti tó, ó tilẹ̀ ti pọ̀jù fún ohun tí wọ́n nílò láti fi ṣe iṣẹ́ náà.
8 Àwọn tí wọ́n mọ iṣẹ́ jù lára àwọn òṣìṣẹ́ náà kọ́ ibi mímọ́ náà pẹlu aṣọ títa mẹ́wàá. Aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ati aṣọ ẹlẹ́pa ati elése àlùkò ati aṣọ pupa fòò ni wọ́n fi ṣe àwọn aṣọ títa náà, wọ́n sì ya àwòrán kerubu sára rẹ̀; wọn fi dárà sí i.
9 Gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, gbogbo wọn rí bákan náà.
10 Ó rán marun-un ninu àwọn aṣọ títa náà pọ̀, ó sì rán marun-un yòókù pọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
11 Ó mú aṣọ aláwọ̀ aró, wọ́n fi rán ojóbó sára aṣọ títa tí ó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ kinni, wọ́n sì tún rán ojóbó sára aṣọ títa tó kángun síta ninu àránpọ̀ aṣọ keji bákan náà.
12 Aadọta ojóbó ni wọ́n rán mọ́ àránpọ̀ aṣọ títa kinni, aadọta ojóbó náà ni wọ́n sì rán mọ́ etí àránpọ̀ aṣọ títa keji, àwọn ojóbó náà dojú kọ ara wọn.