6 Ọlọrun pàṣẹ pé kí awọsanma wà láàrin omi, kí ó pín omi sí ọ̀nà meji, kí ó sì jẹ́ ààlà láàrin omi tí ó wà lókè awọsanma náà ati èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.
7 Ọlọrun dá awọsanma, ó fi ya omi tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ kúrò lára èyí tí ó wà lókè rẹ̀, ó sì rí bẹ́ẹ̀.
8 Ọlọrun sọ awọsanma náà ní ojú ọ̀run. Ilẹ̀ ṣú, ilẹ̀ sì tún mọ́, ó di ọjọ́ keji.
9 Ọlọrun pàṣẹ pé kí omi tí ó wà lábẹ́ ọ̀run wọ́jọ pọ̀ sí ojú kan, kí ìyàngbẹ ilẹ̀ lè farahàn, ó sì rí bẹ́ẹ̀.
10 Ó sọ ìyàngbẹ ilẹ̀ náà ní ilẹ̀, ó sì sọ omi tí ó wọ́jọ pọ̀ ní òkun. Ó wò ó, ó sì rí i pé ó dára.
11 Ọlọrun pàṣẹ pé kí ilẹ̀ hu koríko jáde oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ń so èso tí ó ní irúgbìn ninu, ó sì rí bẹ́ẹ̀.
12 Ilẹ̀ bá hu koríko jáde, oríṣìíríṣìí ohun ọ̀gbìn ati ewéko tí ń so ati oríṣìíríṣìí igi eléso tí ó ní irúgbìn ninu. Ọlọrun wò wọ́n, ó sì rí i pé wọ́n dára.