1 Láti ibẹ̀ ni Abrahamu ti lọ sí agbègbè Nẹgẹbu, ó sì ń gbé Gerari, ní ààrin Kadeṣi ati Ṣuri.
2 Abrahamu sọ fún àwọn ará Gerari pé arabinrin òun ni Sara aya rẹ̀, Abimeleki, ọba Gerari bá ranṣẹ lọ mú Sara.
3 Ṣugbọn Ọlọrun tọ Abimeleki wá lóru lójú àlá, ó sì wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀! Ikú ti pa ọ́ tán báyìí, nítorí pé obinrin tí o mú sọ́dọ̀, aya aláya ni.”
4 Ṣugbọn Abimeleki kò tíì bá Sara lòpọ̀ rárá, ó bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “OLUWA, o wá lè pa àwọn eniyan aláìṣẹ̀ bí?
5 Ṣebí ẹnu ara rẹ̀ ni ó fi sọ pé arabinrin òun ni, tí obinrin náà sì sọ pé arakunrin òun ni. Ohun tí mo ṣe tí ó di ẹ̀ṣẹ̀ yìí, òtítọ́ inú ati àìmọ̀ ni mo fi ṣe é.”
6 Ọlọrun dá a lóhùn lójú àlá, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé òtítọ́ inú ni o fi ṣe ohun tí o ṣe, èmi ni mo sì pa ọ́ mọ́ tí n kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ mí, ìdí sì nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o fọwọ́ kàn án.