10 Iranṣẹ náà mú mẹ́wàá ninu àwọn ràkúnmí oluwa rẹ̀, ó gba oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn àtàtà lọ́wọ́ oluwa rẹ̀, ó jáde lọ sí ilẹ̀ Mesopotamia, sí ìlú Nahori.
11 Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ní déédé ìgbà tí àwọn obinrin máa ń jáde lọ pọn omi, ó mú kí àwọn ràkúnmí rẹ̀ kúnlẹ̀ lẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá kànga kan,
12 ó sì gbadura báyìí pé “Ìwọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, jọ̀wọ́, ṣe ọ̀nà mi ní rere lónìí, kí o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, oluwa mi.
13 Bí mo ti dúró lẹ́bàá kànga yìí, tí àwọn ọdọmọbinrin ìlú yìí sì ń jáde wá láti pọn omi,
14 jẹ́ kí ọmọbinrin tí mo bá sọ fún pé jọ̀wọ́ sọ ìkòkò omi rẹ kalẹ̀ kí o fún mi ní omi mu, tí ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo sì fún àwọn ràkúnmí rẹ mu pẹlu,’ jẹ́ kí olúwarẹ̀ jẹ́ ẹni náà tí o yàn fún Isaaki, iranṣẹ rẹ. Èyí ni n óo fi mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí oluwa mi.”
15 Kí ó tó dákẹ́ adura rẹ̀ ni Rebeka ọmọ Betueli yọ sí i pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Nahori ni Betueli jẹ́, tí Milika bí fún un. Nahori yìí jẹ́ arakunrin Abrahamu.
16 Arẹwà wundia ni Rebeka, kò sì tíì mọ ọkunrin. Bí ó ti dé, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó pọn omi rẹ̀, ó sì jáde.