1 Ní àkókò kan, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ sí ìyàn tí ó mú ní ìgbà Abrahamu. Isaaki bá tọ Abimeleki ọba àwọn ará Filistini lọ ní Gerari.
2 Kí ó tó lọ sí Gerari, Ọlọrun farahàn án, ó sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ lọ sí Ijipti, kí ó máa gbé ilẹ̀ tí òun sọ fún un.
3 Ọlọrun ní, “Máa gbé ilẹ̀ yìí, n óo wà pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ, nítorí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún ní ilẹ̀ wọnyi, n óo sì mú ìlérí mi fún Abrahamu, baba rẹ ṣẹ.
4 N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ wọnyi. Nípasẹ̀ wọn ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé,
5 nítorí pé Abrahamu gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo òfin ati ìlànà mi mọ́ patapata.”