31 Òun náà se oúnjẹ aládùn, ó gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó wí fún un pé, “Baba mi, dìde, kí o jẹ ninu ẹran tí èmi ọmọ rẹ pa, kí o lè súre fún mi.”
32 Isaaki, baba rẹ̀ bi í pé, “Ìwọ ta ni?” Esau bá dá a lóhùn pé, “Èmi ọmọ rẹ ni. Èmi, Esau, àkọ́bí rẹ.”
33 Ara Isaaki bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n gidigidi, ó wí pé, “Ta ló ti kọ́ pa ẹran tí ó gbé e tọ̀ mí wá, tí mo jẹ gbogbo rẹ̀ tán kí o tó dé? Mo sì ti súre fún un. Láìsí àní àní, ìre náà yóo mọ́ ọn.”
34 Nígbà tí Esau gbọ́ ohun tí baba rẹ̀ sọ, ó fi igbe ta, ó sọkún kíkorò, ó wí pé, “Baba mi, súre fún èmi náà.”
35 Ṣugbọn Isaaki dáhùn pé, “Àbúrò rẹ ti wá pẹlu ẹ̀tàn, ó sì ti gba ìre rẹ lọ.”
36 Esau bá dáhùn pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ̀ nítòótọ́. Ó di ìgbà keji tí yóo fi èrú gba ohun tíí ṣe tèmi. Ó ti kọ́kọ́ gba ipò àgbà lọ́wọ́ mi, ó tún wá jí ìre mi gbà lọ.” Esau bá bèèrè lọ́wọ́ baba rẹ̀ pé, “Ṣé o kò wá fi ẹyọ ìre kan pamọ́ fún mi ni?”
37 Isaaki dá a lóhùn, ó ní, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ, gbogbo àwọn arakunrin rẹ̀ ni mo sì ti fún un láti fi ṣe iranṣẹ, mo ti fún un ní ọ̀pọ̀ ọkà ati ọtí waini. Kí ló tún wá kù tí mo lè ṣe fún ọ, ọmọ mi?”