1 Jakọbu ranṣẹ pe àwọn ọmọ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ kó ara yín jọ kí n lè sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ si yín ní ọjọ́ iwájú fún yín.
2 Ẹ péjọ kí ẹ gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,kí ẹ sì fetí sí ọ̀rọ̀ Israẹli, baba yín.
3 Reubẹni, ìwọ ni àkọ́bí mi,agbára mi, ati àkọ́so èso agbára mi,ìwọ tí o ní ìgbéraga jùlọ,tí o sì lágbára jùlọ ninu àwọn ọmọ mi.
4 Ìwọ tí o dàbí ìkún omi tí ń bì síwá sẹ́yìn,o kò ní jẹ́ olórí, nítorí pé o ti bá obinrin mi lòpọ̀,o sì ti sọ ibùsùn èmi baba rẹ di aláìmọ́.
5 Simeoni ati Lefi jẹ́ arakunrin,ìlò ìkà ati ipá ni wọ́n ń lo idà wọn.
6 Orí mi má jẹ́ kí n bá wọn pa ìmọ̀ pọ̀,ẹlẹ́dàá mi má sì jẹ́ kí n bá wọn kẹ́gbẹ́.Nítorí wọn a máa fi ibinu paniyan,wọn a sì máa ṣá akọ mààlúù lọ́gbẹ́ bí ohun ìdárayá.
7 Ìfibú ni ibinu wọn, nítorí pé ó le,ati ìrúnú wọn, nítorí ìkà ni wọ́n.N óo pín wọn káàkiri ilẹ̀ Jakọbu,n óo sì fọ́n wọn ká ààrin àwọn eniyan Israẹli.