15 Bí mo bá ṣe àìdára, mo gbé,ṣugbọn bí mo ṣe dáradára, n kò lè yangàn,nítorí ìbànújẹ́ ati ìtìjú bò mí mọ́lẹ̀.
16 Bí mo bá ṣe àṣeyọrí,o óo máa lépa mi bíi kinniun;ò ń lo agbára rẹ láti pa mí lára.
17 O wá àwọn ẹlẹ́rìí tuntun pé kí wọ́n dojú kọ mí,O tún bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí mi lọpọlọpọ,O mú kí ogun mìíràn dó tì mí.
18 “Kí ló dé tí o fi mú mi jáde láti inú ìyá mi?Ìbá sàn kí n ti kú,kí ẹnikẹ́ni tó rí mi.
19 Wọn ìbá má bí mi rárá,kí wọ́n gbé mi láti inú ìyá mi lọ sinu ibojì.
20 Ṣebí ọjọ́ díẹ̀ ni mo níláti lò láyé?Fi mí sílẹ̀ kí n lè ní ìtura díẹ̀,
21 kí n tó pada síbi tí mo ti wá,sí ibi òkùnkùn biribiri,