1 Nígbà náà ni Jobu dáhùn pé,
2 “Lónìí, ìráhùn mi tún kún fún ẹ̀dùn,ọwọ́ Ọlọrun ń le lára mi,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mò ń kérora.
3 Áà! Ìbá jẹ́ pé mo mọ ibi tí mo ti lè rí i ni,ǹ bá lọ siwaju ìtẹ́ rẹ̀!
4 Ǹ bá ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ̀,gbogbo ẹnu ni ǹ bá fi ṣàròyé.
5 Ǹ bá gbọ́ èsì tí yóo fún mi,ati ọ̀rọ̀ tí yóo sọ fún mi.
6 Ṣé yóo gbéjà kò mí pẹlu agbára ńlá rẹ̀?Rárá o, yóo gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
7 Ibẹ̀ ni olódodo yóo ti lè sọ ti ẹnu rẹ̀,yóo sì dá mi sílẹ̀ títí lae.
8 “Wò ó! Mo lọ siwaju, kò sí níbẹ̀,mo pada sẹ́yìn, n kò gbúròó rẹ̀.
9 Mo wo apá ọ̀tún, n kò rí i,mo wo apá òsì, kò sí níbẹ̀.
10 Ṣugbọn ó mọ gbogbo ọ̀nà mi,ìgbà tí ó bá dán mi wò tán,n óo yege bíi wúrà.
11 Mò ń tẹ̀lé e lẹ́yìn, mo súnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí,n kò tíì yipada kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
12 N kò tíì yapa kúrò ninu àṣẹ tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde,mò ń pa wọ́n mọ́ ninu ọkàn mi.
13 “Ṣugbọn Ọlọrun kìí yipada,kò sí ẹni tí ó lè yí i lọ́kàn pada.Ohun tí ó bá fẹ́ gan-an ni yóo ṣe.
14 Yóo ṣe ohun tí ó ti pinnu láti ṣe fún mi ní àṣeyọrí,ati ọpọlọpọ nǹkan bẹ́ẹ̀ yòókùtí ó tún ní lọ́kàn láti ṣe fún mi.
15 Ìdí nìyí tí ẹ̀rù fi bà mí níwájú rẹ̀,tí mo bá ro nǹkan wọnyi, jìnnìjìnnì rẹ̀ a bò mí.
16 Ọlọrun ti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi,Olodumare ti dẹ́rùbà mí.
17 Nítorí pé òkùnkùn yí mi ká,òkùnkùn biribiri sì ṣú bò mí lójú.