Jobu 4 BM

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Kinni

1 Nígbà náà ni Elifasi, ará Temani, dá Jobu lóhùn, ó ní:

2 “Bí eniyan bá bá ọ sọ̀rọ̀,ṣé kò ní bí ọ ninu?Àbí eniyan ha lè dákẹ́ bí?

3 O ti kọ́ ọpọlọpọ eniyan,o ti fún aláìlera lókun.

4 O ti fi ọ̀rọ̀ gbé àwọn tí wọn ń ṣubú ró,ọ̀rọ̀ rẹ ti fún orúnkún tí ń yẹ̀ lọ lágbára.

5 Ṣugbọn nisinsinyii tí ọ̀rọ̀ kàn ọ́,o kò ní sùúrù;Ó dé bá ọ, ìdààmú bá ọ.

6 Ṣé ìbẹ̀rù Ọlọrun kò tó ìgboyà fún ọ?Àbí ìwà òdodo rẹ kò fún ọ ní ìrètí?

7 “Ìwọ náà ronú wò,ṣé aláìṣẹ̀ kan ṣègbé rí?Tabi olódodo kan parun rí?

8 Bí èmi ti rí i sí ni pé,ẹni tí ó kọ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ ebè,tí ó sì gbin wahala,yóo kórè ìyọnu.

9 Èémí Ọlọrun níí pa wọ́n run,ninu ibinu rẹ̀, wọ́n a sì ṣègbé.

10 Ọlọrun fi òpin sí igbe kinniun,ati bíbú tí kinniun ń bú ramúramù,ó sì wọ́ àwọn ẹgbọ̀rọ̀ kinniun léyín.

11 Kinniun alágbára a máa kú,nítorí àìrí ẹran pa jẹ,àwọn ọmọ abo kinniun a sì fọ́nká.

12 “Nisinsinyii wọ́n fọ̀rọ̀ kan tó mi létímo gbọ́ wúyẹ́-wúyẹ́ rẹ̀.

13 Ninu ìran lóru,nígbà tí àwọn eniyan sùn fọnfọn,

14 ìbẹ̀rùbojo mú mi,gbogbo ara mi sì ń gbọ̀n rìrì.

15 Ẹ̀mí kan kọjá fìrí níwájú mi,gbogbo irun ara mi sì dìde.

16 Ó dúró jẹ́ẹ́,ṣugbọn n kò mọ̀ bí ó ti rí.Mo ṣá rí kinní kan tí ó dúró;gbogbo nǹkan parọ́rọ́,nígbà náà ni mo gbọ́ ohùn kan tí ó wí pé,

17 ‘Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè jẹ́ olódodo níwájú Ọlọrun?Tabi kí eniyan jẹ́ mímọ́ níwájú Ẹlẹ́dàá rẹ̀?

18 Nígbà tí ó jẹ́ pé,Ọlọrun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn iranṣẹ rẹ̀,a sì máa bá àṣìṣe lọ́wọ́ àwọn angẹli rẹ̀;

19 mélòó mélòó wá ni eniyan tí a fi amọ̀ mọ,tí ìpìlẹ̀ wọn jẹ́ erùpẹ̀,tí a lè pa bíi kòkòrò lásánlàsàn.

20 Eniyan lè wà láàyè ní òwúrọ̀kí ó kú kí ó tó di ọjọ́ alẹ́,wọn a parun títí laeláìsí ẹni tí yóo bìkítà.

21 Bí a bá gba gbogbo ohun tí wọ́n fẹ̀mí tẹ̀,ṣé wọn kò ní kú bí aláìgbọ́n?’