Jobu 3 BM

Jobu Ráhùn sí Ọlọrun

1 Nígbà tí ó yá, Jobu bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó fi ọjọ́ ìbí ara rẹ̀ bú.

2 Ó ní:

3 “Ègún ni fún ọjọ́ tí wọ́n bí mi,ati alẹ́ tí wọ́n lóyún mi.

4 Jẹ́ kí ọjọ́ náà ṣókùnkùn biribiri!Kí Ọlọrun má ṣe ka ọjọ́ náà sí,kí ìmọ́lẹ̀ má ṣe tàn sí i mọ́.

5 Ṣe é ní ọjọ́ ìṣúdudu,ati òkùnkùn biribiri.Kí ìkùukùu ṣíji bò ó,kí òkùnkùn sì dẹ́rù bà á.

6 Kí òkùnkùn ṣú bo alẹ́ ọjọ́ náà biribiri,kí á yọ ọ́ kúrò ninu àwọn ọjọ́tí ó wà ninu ọdún,kí á má sì ṣe kà á kúnàwọn ọjọ́ tí wọ́n wà ninu oṣù.

7 Kí alẹ́ ọjọ́ náà di òfo,kí á má ṣe gbọ́ ìró ayọ̀ ninu rẹ̀ mọ́.

8 Kí àwọn tí wọ́n ń fi ọjọ́ gégùn-ún fi gégùn-ún,àní àwọn tí wọ́n lè fi àṣẹ rú Lefiatani sókè.

9 Kí ìràwọ̀ òwúrọ̀ rẹ̀ ṣókùnkùn,kí ìrètí rẹ̀ fún ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ já sí òfo,kí ó má rí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ mọ́;

10 nítorí pé kò sé inú ìyá minígbà tí ó fẹ́ bí mi,bẹ́ẹ̀ ni kò sì mú ibi kúrò lọ́nà mi.

11 “Kí ló dé tí n kò kúnígbà tí ìyá mi ń rọbí lọ́wọ́, tí ó fẹ́ bí mi,tabi kí n kú, lẹsẹkẹsẹ tí wọ́n bí mi?

12 Kí ló dé tí ìyá mi gbé mi lẹ́sẹ̀?Kí ló dé tí ó fi fún mi lọ́mú?

13 Ǹ bá ti dùbúlẹ̀,ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́;ǹ bá ti sùn,ǹ bá sì ti máa sinmi

14 pẹlu àwọn ọba ati àwọn ìgbìmọ̀ àgbáyé, tí wọ́n ti sùn,àwọn tí wọ́n tún àlàpà kọ́ fún ara wọn;

15 tabi pẹlu àwọn ọmọ aládé tí wọ́n ní wúrà,tí fadaka sì kún ilé wọn.

16 Tabi kí n rí bí ọmọtí a bí ní ọjọ́ àìpé,tí a bò mọ́lẹ̀ láì tíì lajú sáyé.

17 Níbi tí àwọn oníṣẹ́ ibi kò ti lágbára mọ́,tí àwọn tí gbogbo nǹkan ti sú gbé ń sinmi.

18 Níbẹ̀, àwọn ẹlẹ́wọ̀n ń gbé pọ̀ pẹlu ìrọ̀rùn,wọn kò sì gbọ́ ohùn akóniṣiṣẹ́ mọ́.

19 Àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki pataki jọ wà níbẹ̀,àwọn ẹrú sì bọ́ lọ́wọ́ oluwa wọn.

20 “Kí ló dé tí a fi ìmọ́lẹ̀fún ẹni tí ń kérora,tí a fi ẹ̀mí fún ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́;

21 tí ó ń wá ikú,ṣugbọn tí kò rí;tí ó ń wá ikú lójú mejeejiju ẹni tí ń wá ìṣúra tí a fi pamọ́ lọ?

22 Àwọn tí inú wọn ìbá dùn lọpọlọpọbí wọ́n bá rí ẹni gbé wọn sin.

23 Kí ló dé tí a fi fi ìmọ́lẹ̀fún ẹni tí ọ̀nà dàrú mọ́ lójú;ẹni tí Ọlọrun ti tì sinu àhámọ́?

24 Nítorí ìmí ẹ̀dùn di oúnjẹ fún mi,ìráhùn mi sì ń tú jáde bí omi.

25 Ohun tí mo bẹ̀rù jù ti dé bá mi,ohun tí ń fò mí láyà ti ṣẹlẹ̀ sí mi.

26 N kò ní alaafia,bẹ́ẹ̀ ni ara kò rọ̀ mí,n kò sì ní ìsinmi, àfi ìyọnu.”