Jobu 39 BM

1 “Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ?Ṣé o ti ká àgbọ̀nrín mọ́ ibi tí ó ti ń bímọ rí?

2 Ǹjẹ́ o lè ka iye oṣù tí wọ́n fi ń lóyún?Tabi o mọ ìgbà tí wọ́n bímọ?

3 Ǹjẹ́ o mọ ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀,tí wọ́n sì bímọ?

4 Àwọn ọmọ wọn á di alágbára,wọn á dàgbà ninu pápá,wọn á sì lọ, láìpadà wá sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn mọ́.

5 “Ta ló fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ lómìniratí ó sì tú ìdè rẹ̀?

6 Mo fi inú pápá ṣe ilé rẹ̀,ilẹ̀ oníyọ̀ sì di ibùgbé rẹ̀.

7 Ó ń pẹ̀gàn ìdàrúdàpọ̀ inú ìlú ńlá,kò gbọ́ ariwo àwọn tí wọn ń fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ṣiṣẹ́.

8 Ó ń rìn káàkiri àwọn òkè bí ibùjẹ rẹ̀,ó sì ń wá ewéko tútù kiri.

9 “Ṣé ẹfọ̀n ṣetán láti sìn ọ́?Ṣé yóo wá sùn ní ibùjẹ ẹran rẹ lálẹ́?

10 Ṣé o lè so àjàgà mọ́ ọn lọ́rùn ní poro oko,tabi kí ó máa kọ ebè tẹ̀lé ọ?

11 Ṣé o lè gbẹ́kẹ̀lé e nítorí pé agbára rẹ̀ pọ̀,tabi kí o fi iṣẹ́ rẹ sílẹ̀ fún un láti ṣe?

12 Ṣé o ní igbagbọ pé yóo pada,ati pé yóo ru ọkà rẹ̀ wá sí ibi ìpakà rẹ?

13 “Ògòǹgò lu ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ninu ọláńlá rẹ̀,ṣugbọn kò lè fò bí ẹyẹ àkọ̀?

14 Ó yé ẹyin rẹ̀ sórí ilẹ̀,kí ooru ilẹ̀ lè mú wọn,

15 ó gbàgbé pé ẹnìkan le tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ kí wọn sì fọ́,ati pé ẹranko ìgbẹ́ lè fọ́ wọn.

16 Ògòǹgò kò náání àwọn ọmọ rẹ̀,ó ń ṣe sí wọn bí ẹni pé kì í ṣe òun ló bí wọn,kò bìkítà bí wahala rẹ̀ tilẹ̀ já sí asán;

17 nítorí pé Ọlọrun kò fún un ní ọgbọ́n ati òye.

18 Ṣugbọn nígbà tí ó bá ṣetán ati sáré,a máa fi ẹṣin ati ẹni tí ó gùn ún ṣe yẹ̀yẹ́.

19 “Ṣé ìwọ ni o fún ẹṣin lágbára,tí o sì fi agbára ṣe gọ̀gọ̀ sí i lọ́rùn?

20 Ṣé ìwọ lò ń mú kí ó máa ta pọ́nún bí eṣú,tí kíké rẹ̀ sì ń bani lẹ́rù?

21 Ó fẹsẹ̀ walẹ̀ ní àfonífojì,ó yọ̀ ninu agbára rẹ̀,ó sì jáde lọ sí ojú ogun.

22 Kò mọ ẹ̀rù, ọkàn rẹ̀ kì í rẹ̀wẹ̀sì,bẹ́ẹ̀ ni kì í sá fún idà.

23 Ó gbé apó ọfà sẹ́yìn, tí ń mì pẹkẹpẹkẹ, pẹlu ọ̀kọ̀tí ń kọ mànà, ati apata.

24 Ó ń fi ẹnu họlẹ̀ pẹlu ìgboyà ati ìwàǹwára,nígbà tí ipè dún, ara rẹ̀ kò balẹ̀.

25 Nígbà tí fèrè dún, ó kọ, ‘Hàáà!’Ó ń gbóòórùn ogun lókèèrè,ó ń gbọ́ igbe ọ̀gágun tí ń pàṣẹ.

26 “Ṣé ìwọ lo kọ́ àwòdì bí a ti í fò,tí ó fi na ìyẹ́ rẹ̀ sí ìhà gúsù?

27 Ṣé ìwọ ni o pàṣẹ fún idì láti fò lọ sókè,tabi láti tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sórí òkè gíga?

28 Ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí òkè gíga-gíga,ninu pàlàpálá àpáta.

29 Níbẹ̀ ni ó ti ń ṣọ́ ohun tí yóo pa,ojú rẹ̀ a sì rí i láti òkèèrè réré.

30 Àwọn ọmọ rẹ̀ a máa mu ẹ̀jẹ̀,ibi tí òkú bá sì wà ni idì máa ń wà.”