Jobu 13 BM

1 “Gbogbo ìwọ̀nyí ni ojú mi ti rí rí,tí etí mi ti gbọ́, tí ó sì yé mi.

2 Ohun tí ẹ mọ̀ wọnyi, èmi náà mọ̀ ọ́n,ẹ kò sàn jù mí lọ.

3 Ṣugbọn n óo bá Olodumare sọ̀rọ̀,Ọlọrun ni mo sì fẹ́ bá rojọ́.

4 Ẹ̀yin òpùrọ́ ati ẹlẹ́tàn wọnyi,ẹ̀yin oníṣègùn tí ẹ kò lè wonisàn.

5 Ẹ̀ bá jẹ́ pa ẹnu yín mọ́ ni,à bá pè yín ní ọlọ́gbọ́n!

6 Nisinsinyii ẹ gbọ́ èrò ọkàn mi,kí ẹ sì fetísí àròyé mi.

7 Ṣé ẹ óo máa parọ́ ní orúkọ Ọlọrun ni,kí ẹ sì máa sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní orúkọ rẹ̀?

8 Ṣé ẹ fẹ́ máa ṣe ojuṣaaju fún Ọlọrun ni?Tabi ẹ fẹ́ jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀?

9 Ṣé ẹ óo yege bí ó bá dán yín wò?Tabi ẹ lè tan Ọlọrun bí ẹni tan eniyan?

10 Dájúdájú, yóo ba yín wí,bí ẹ bá ń ṣe ojuṣaaju níkọ̀kọ̀.

11 Ògo rẹ̀ yóo dẹ́rùbà yín,jìnnìjìnnì rẹ̀ yóo dà bò yín.

12 Àwọn òwe yín kò wúlò,àwíjàre yín kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

13 Ẹ dákẹ́, kí n ráyè sọ tèmi,kí ohun tí yóo bá dé bá mi dé bá mi.

14 N óo dijú, n óo fi ẹ̀mí ara mi wéwu.

15 Wò ó, yóo pa mí; n kò ní ìrètí;sibẹ n óo wí àwíjàre tèmi níwájú rẹ̀.

16 Èyí ni yóo jẹ́ ìgbàlà mi,nítorí pé ẹni tí kò mọ Ọlọrun,kò ní lè dúró níwájú rẹ̀.

17 Fetí sílẹ̀ dáradára sí ọ̀rọ̀ mi,kí o sì gbọ́ mi ní àgbọ́yé.

18 Wò ó, mo ti múra ẹjọ́ mi sílẹ̀;mo sì mọ̀ pé n óo gba ìdáláre.

19 Ta ni yóo wá bá mi rojọ́?Bí ó bá wá, n óo dákẹ́, n óo sì kú.

20 Nǹkan meji péré ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi,n kò sì ní farapamọ́ fún ọ:

21 ká ọwọ́ ibinu rẹ kúrò lára mi,má sì ṣe jẹ́ kí jìnnìjìnnì rẹ dà bò mí.

22 Lẹ́yìn náà, sọ̀rọ̀, n óo sì fèsì;tabi kí o jẹ́ kí èmi sọ̀rọ̀, kí o sì fún mi lésì.

23 Báwo ni àìdára ati ẹ̀ṣẹ̀ mi ti pọ̀ tó?Jẹ́ kí n mọ ẹ̀ṣẹ̀ mi, ati ibi tí mo ti kọjá ààyè mi.

24 Kí ló dé tí o fi fi ara pamọ́ fún mití o kà mí kún ọ̀tá rẹ?

25 Ṣé o óo máa dẹ́rùba ewé lásán tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri,tabi o óo máa lépa ìyàngbò gbígbẹ?

26 O ti kọ àkọsílẹ̀ burúkú nípa mi,o mú mi jìyà ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi.

27 O kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí mi lẹ́sẹ̀,ò ń ṣọ́ ìrìn ẹsẹ̀ mi,o sì pa ààlà tí n kò gbọdọ̀ rékọjá.

28 Eniyan ń ṣègbé lọ bí ohun tí ó ń jẹrà,bí aṣọ tí ikán ti mu.