Jobu 32 BM

Ọ̀rọ̀ Elihu

1 Àwọn ọkunrin mẹtẹẹta náà kò dá Jobu lóhùn mọ́, nítorí pé ó jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀.

2 Elihu, ọmọ Barakeli, ará Busi, ní ìdílé Ramu bá bínú sí Jobu, nítorí pé ó dá ara rẹ̀ láre dípò Ọlọrun.

3 Ó bínú sí àwọn ọ̀rẹ́ Jobu mẹtẹẹta pẹlu, nítorí pé wọn kò mọ èsì tí wọ́n lè fún Jobu mọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dá a lẹ́bi.

4 Elihu ti fẹ́ bá Jobu sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn ó dákẹ́, nítorí àwọn àgbà tí wọ́n jù ú lọ ni wọ́n ń sọ̀rọ̀.

5 Ṣugbọn nígbà tí Elihu rí i pé àwọn mẹtẹẹta kò lè fún Jobu lésì mọ́, inú bí i.

6 Ó ní,“Àgbàlagbà ni yín, ọmọde sì ni mí,nítorí náà ni ojú fi ń tì mí,tí ẹ̀rù sì ń bà mí láti sọ èrò ọkàn mi.

7 Mo ní kí ẹ̀yin àgbà sọ̀rọ̀,kí ọ̀rọ̀ yín sì fa ọgbọ́n yọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí yín.

8 Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu eniyan,tíí ṣe èémí Olodumare,ni ó ń fún eniyan ní ìmọ̀.

9 Kì í ṣe àwọn àgbà nìkan ni wọ́n gbọ́n,tabi pé arúgbó nìkan ni ó mọ òye ohun tó tọ́, tó yẹ.

10 Nítorí náà, ‘Ẹ fetí sílẹ̀,kí èmi náà lè sọ èrò ọkàn mi.’

11 “Mo farabalẹ̀ nígbà tí ẹ̀yin ń sọ̀rọ̀,mo fetí sí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n yín,nígbà tí ẹ̀ ń ronú ohun tí ẹ fẹ́ sọ,

12 Mo farabalẹ̀ fun yín,ṣugbọn kò sí ẹnikẹ́ni ninu yín tí ó lè ko Jobu lójú,kí ó sì fi àṣìṣe rẹ̀ hàn án,tabi kí ó fún un lésì àwọn àwíjàre rẹ̀.

13 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má baà wí pé, ‘A ti di ọlọ́gbọ́n,Ọlọrun ló lè ṣe ìdájọ́ rẹ̀, kì í ṣe eniyan.’

14 Èmi kọ́ ni Jobu ń bá wí, ẹ̀yin ni,n kò sì ní dá a lóhùn bí ẹ ṣe dá a lóhùn.

15 “Ọkàn wọn dàrú, wọn kò sì lè fèsì mọ́,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ohun kan láti sọ.

16 Ṣé kí n dúró,nítorí pé wọ́n dúró láìfèsì?

17 Èmi náà óo fèsì lé e,n óo sì sọ èrò ọkàn tèmi.

18 Mo ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ,Ṣugbọn ẹ̀mí tí ó wà ninu mi ló ń kó mi ní ìjánu.

19 Ọ̀rọ̀ kún inú mi bí ọtí inú ìgò,ó fẹ́ ru síta bí ọtí inú ìgò aláwọ.

20 Mo níláti sọ̀rọ̀ kí ara lè rọ̀ mí,mo gbọdọ̀ la ẹnu mi kí n sì dáhùn.

21 N kò ní ṣe ojuṣaaju ẹnikẹ́ni,bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ní gbèjà eniyan.

22 Nítorí n kò mọ bí wọ́n ṣe ń pọ́n eniyan,kí Ẹlẹ́dàá mi má baà pa mí run ní kíá.