Jobu 35 BM

1 Elihu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní,

2 “Jobu, ṣé o rò pé ó tọ̀nà,kí o máa sọ pé, ‘Ọ̀nà mi tọ́ níwájú Ọlọrun?’

3 Kí o tún máa bèèrè pé, ‘Anfaani wo ni mo ní?Tabi kí ni mo fi sàn ju ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀ lọ?’

4 N óo dá ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lóhùn.

5 Gbójú sókè kí o wo ojú ọ̀run,ati àwọn ìkùukùu tí ó wà lókè.

6 Bí o bá dẹ́ṣẹ̀, kò ṣe Ọlọrun ní àìrójú,bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bá pọ̀, kò jámọ́ nǹkankan fún un.

7 Bí o bá jẹ́ olódodo,kí ni ó dà fún Ọlọrun,tabi kí ni ó ń rí gbà lọ́wọ́ rẹ?

8 Àwọn eniyan burúkú bíì rẹ, ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ lè pa lára,àwọn ọmọ eniyan ni òdodo rẹ sì lè jẹ́ anfaani fún.

9 “Àwọn eniyan ń kígbe nítorí ọpọlọpọ ìnira,wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́,nítorí àwọn alágbára ń tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.

10 Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó bèèrè pé,‘Níbo ni Ọlọrun Ẹlẹ́dàá mi wà,tíí fún ni ní orin ayọ̀ lóru,

11 ẹni tí ó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ju àwọn ẹranko lọ,Ó sì fún wa ní ọgbọ́n ju àwọn ẹyẹ lọ?’

12 Wọ́n kígbe níbẹ̀ ṣugbọn kò dá wọn lóhùn,nítorí ìgbéraga àwọn eniyan burúkú.

13 Dájúdájú Ọlọrun kì í gbọ́ igbe asán,Olodumare kò tilẹ̀ náání rẹ̀.

14 Kí á má tilẹ̀ sọ ti ìwọ Jobu, tí o sọ péo kò rí i,ati pé ẹjọ́ rẹ wà níwájú rẹ̀,o sì ń dúró dè é!

15 Ṣugbọn nisinsinyii, nítorí pé inú kì í bí i kí ó jẹ eniyan níyà,bẹ́ẹ̀ ni kò ka ẹ̀ṣẹ̀ kún lọ títí.

16 Jobu kàn ń la ẹnu,ó sì ń sọ̀rọ̀ lásán ni.Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pọ̀, ṣugbọn kò mú ọgbọ́n lọ́wọ́.”