Jobu 12 BM

1 Jobu dáhùn pé:

2 “Láìsí àní àní,ẹ̀yin ni agbẹnusọ gbogbo eniyan,bí ẹ bá jáde láyé,ọgbọ́n kan kò tún ní sí láyé mọ́.

3 Bí ẹ ti ní ìmọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi náà ní,ẹ kò sàn jù mí lọ.Ta ni kò mọ irú nǹkan, tí ẹ̀ ń sọ yìí?

4 Mo wá di ẹlẹ́yà lójú àwọn ọ̀rẹ́ mi,èmi tí mò ń ké pe Ọlọrun,tí ó sì ń dá mi lóhùn;èmi tí mo jẹ́ olódodo ati aláìlẹ́bi,mo wá di ẹlẹ́yà.

5 Lójú ẹni tí ara tù,ìṣòro kì í báni láìnídìí.Lójú rẹ̀, ẹni tí ó bá ṣìṣe ni ìṣòro wà fún.

6 Àwọn olè ń gbé ilé wọn ní alaafia,àwọn tí wọn ń mú Ọlọrun bínú wà ní àìléwu,àwọn tí ó jẹ́ pé agbára wọn ni Ọlọrun wọn.

7 “Ṣugbọn, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹranko, wọn óo sì kọ́ ọ,bi àwọn ẹyẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ;

8 tabi kí o bi àwọn koríko, wọn yóo sì kọ́ ọ,àwọn ẹja inú òkun yóo sì ṣe àlàyé fún ọ.

9 Ta ni kò mọ̀ ninu gbogbo wọnpé OLUWA ló ṣe èyí?

10 Ọwọ́ rẹ̀ ni ìyè gbogbo ẹ̀dá wà,ati ẹ̀mí gbogbo eniyan.

11 Ṣebí etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,ahọ́n a sì máa tọ́ oúnjẹ wò?

12 “Àgbà ló ni ọgbọ́n,àwọn ogbó tí wọ́n ti pẹ́ láyé ni wọ́n ni òye.

13 Ọlọrun ló ni ọgbọ́n ati agbára,tirẹ̀ ni ìmọ̀ràn ati ìmọ̀.

14 Ohun tí Ọlọrun bá wó lulẹ̀,ta ló lè tún un kọ́?Tí ó bá ti eniyan mọ́lé,ta ló lè tú u sílẹ̀?

15 Bí ó bá dáwọ́ òjò dúró, ọ̀gbẹlẹ̀ a dé,bí ó bá sí rọ òjò, omi a bo ilẹ̀.

16 Òun ló ni agbára ati ọgbọ́n,òun ló ni ẹni tí ń tan ni jẹ,òun náà ló ni ẹni tí à ń tàn.

17 Ó pa ọgbọ́n mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu,ó sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.

18 Ó tú àwọn tí àwọn ọba dè mọ́lẹ̀,ó sì so ẹ̀wọ̀n mọ́ àwọn ọba gan-an nídìí.

19 Ó rẹ àwọn alufaa sílẹ̀,ó sì gba agbára lọ́wọ́ àwọn alágbára.

20 Ó pa àwọn agbẹnusọ lẹ́nu mọ́,ó gba ìmọ̀ àwọn àgbààgbà.

21 Ó dójúti àwọn olóyè,ó tú àmùrè àwọn alágbára.

22 Ó mú ohun òkùnkùn wá sí ìmọ́lẹ̀,ó sì tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn biribiri.

23 Òun níí sọ àwọn orílẹ̀-èdè di ńlá,òun náà níí sìí tún pa wọ́n run:Òun níí kó àwọn orílẹ̀-èdè jọ,òun náà níí sì ń tú wọn ká.

24 Ó gba ìmọ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjòyè ní gbogbo ayé,ó sì sọ wọ́n di alárìnká ninu aṣálẹ̀,níbi tí ọ̀nà kò sí.

25 Wọ́n ń táràrà ninu òkùnkùn,ó sì mú kí wọ́n máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n bí ọ̀mùtí.