Jobu 42 BM

1 Jobu bá dá OLUWA lóhùn ó ní:

2 “Mo mọ̀ pé o lè ṣe ohun gbogbo,kò sì sí ohun tí ó lè da ìpinnu rẹ rú.

3 Ta nìyí tí ń fi ìmọ̀ràn pamọ́ láìní òye?Àwọn ohun tí mo sọ kò yé mi,ìyanu ńlá ni wọ́n jẹ́ fún mi,n kò sì mọ̀ wọ́n.

4 O ní kí n tẹ́tí sílẹ̀,nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀,kí n sì dáhùn nígbà tí o bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ mi.

5 Ìró rẹ ni mo gbọ́ tẹ́lẹ̀,ṣugbọn nisinsinyii mo ti rí ọ;

6 nítorí náà, ojú ara mi tì mí,fún ohun tí mo ti sọ,mo sì ronupiwada ninu erùpẹ̀ ati eérú.”

Ìparí

7 Lẹ́yìn ìgbà tí OLUWA ti bá Jobu sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Elifasi ará Temani pé, “Inú ń bí mi sí ìwọ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ mejeeji. Nítorí ẹ kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi, bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.

8 Nítorí náà, mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje lọ sí ọ̀dọ̀ Jobu kí o rú ẹbọ sísun fún ara rẹ; Jobu iranṣẹ mi yóo sì gbadura fún ọ, n óo gbọ́ adura rẹ̀, n kò sì ní ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ. Nítorí o kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi gẹ́gẹ́ bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.”

9 Nítorí náà, Elifasi ará Temani, Bilidadi ará Ṣuha, ati Sofari ará Naama lọ ṣe ohun tí OLUWA sọ fún wọn, OLUWA sì gbọ́ adura Jobu.

10 Lẹ́yìn ìgbà tí Jobu gbadura fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta tán, OLUWA dá ọrọ̀ Jobu pada, ó sì jẹ́ kí ó ní ìlọ́po meji àwọn ohun tí ó ti ní tẹ́lẹ̀.

11 Àwọn arakunrin ati arabinrin Jobu ati àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ pada wá bẹ̀ ẹ́ wò. Wọ́n jẹ àsè ní ilé rẹ̀, wọ́n káàánú rẹ̀, wọ́n sì tù ú ninu, nítorí ohun burúkú tí OLUWA ti mú wá sórí rẹ̀, olukuluku wọn fún un ní owó ati òrùka wúrà kọ̀ọ̀kan.

12 OLUWA bukun ìgbẹ̀yìn Jobu ju ti iṣaaju rẹ̀ lọ, ó ní ẹgbaaje (14,000) aguntan, ẹgbaata (6,000) ràkúnmí, ẹgbẹrun (1,000) àjàgà mààlúù ati ẹgbẹrun (1,000) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

13 Ó tún bí ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta.

14 Ó pe àkọ́bí obinrin ni Jemima, ekeji ni Kesaya, ẹkẹta ni Kereni Hapuki.

15 Kò sì sí ọmọbinrin tí ó lẹ́wà bí àwọn ọmọbinrin Jobu ní gbogbo ayé. Baba wọn sì fún wọn ní ogún láàrin àwọn arakunrin wọn.

16 Lẹ́yìn náà Jobu tún gbé ogoje (140) ọdún sí i láyé, ó rí àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ títí dé ìran kẹrin.

17 Ó di arúgbó kùjọ́kùjọ́ kí ó tó kú.