1 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náàtí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú,tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn,tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́.
2 Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfẹ́ sí òfin OLUWA,a sì máa ṣe àṣàrò lórí rẹ̀ tọ̀sán-tòru.
3 Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odòtí ń so ní àkókò tí ó yẹ,tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀.Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere.
4 Àwọn eniyan burúkú kò rí bẹ́ẹ̀,ṣugbọn wọ́n dàbí fùlùfúlù tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.
5 Nítorí náà àwọn eniyan burúkú kò ní rí ìdáláre,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kò ní le wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
6 Nítorí OLUWA ń dáàbò bo àwọn olódodo,ṣugbọn àwọn eniyan burúkú yóo ṣègbé.