1 Ẹ máa yọ̀ ninu OLUWA, ẹ̀yin olódodo!Yíyin OLUWA ni ó yẹ ẹ̀yin olóòótọ́.
2 Ẹ fi gòjé yin OLUWA,ẹ fi hapu olókùn mẹ́wàá kọ orin sí i.
3 Ẹ kọ orin titun sí i,ẹ fi ohun èlò ìkọrin olókùn dárà,kí ẹ sì hó ìhó ayọ̀.
4 Nítorí ọ̀rọ̀ OLUWA dúró ṣinṣin;òtítọ́ sì ni ó fi ń ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.
5 OLUWA fẹ́ràn òdodo ati ẹ̀tọ́;ayé kún fún ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀.
6 Ọ̀rọ̀ ni OLUWA fi dá ojú ọ̀run,èémí ẹnu rẹ̀ ni ó sì fi dá oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀.
7 Ó wọ́ gbogbo omi òkun jọ bí òkìtì;ó pa gbogbo omi inú àwọn ibú pọ̀ bí ẹni pé ó rọ ọ́ sinu àgbá ńlá.
8 Kí gbogbo ayé bẹ̀rù OLUWA,kí gbogbo aráyé dúró níwájú rẹ̀ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù!
9 Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà;ó pàṣẹ, ayé sì dúró.
10 OLUWA sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè di asán;ó sì mú kí ètò àwọn eniyan já sófo.
11 Ètò OLUWA wà títí lae,èrò ọkàn rẹ̀ sì wà láti ìran dé ìran.
12 Ayọ̀ ń bẹ fún orílẹ̀-èdè tí OLUWA jẹ́ Ọlọrun wọn,àní àwọn eniyan tí ó yàn gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀!
13 OLUWA bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,ó rí gbogbo eniyan;
14 láti orí ìtẹ́ rẹ̀ tí ó gúnwà sí,ó wo gbogbo aráyé.
15 Òun ni ó dá ọkàn gbogbo wọn,tí ó sì ń mójútó gbogbo ìṣe wọn.
16 Kì í ṣe pípọ̀ tí àwọn ọmọ ogun pọ̀ ní ń gba ọba là;kì í sì í ṣe ọ̀pọ̀ agbára níí gba jagunjagun là.
17 Asán ni igbẹkẹle agbára ẹṣin ogun;kìí ṣe agbára tí ẹṣin ní, ló lè gbani là.
18 Wò ó! OLUWA ń ṣọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,àní àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀,
19 kí ó lè gba ọkàn wọn lọ́wọ́ ikú,kí ó sì mú wọn wà láàyè lákòókò ìyàn.
20 Ọkàn wa ní ìrètí lọ́dọ̀ OLUWA;òun ni olùrànlọ́wọ́ ati ààbò wa.
21 A láyọ̀ ninu rẹ̀,nítorí pé a gbẹ́kẹ̀lé orúkọ mímọ́ rẹ̀.
22 OLUWA, jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ wà lórí wabí a ti gbẹ́kẹ̀lé ọ.