Orin Dafidi 40 BM

Orin ìyìn

1 Sùúrù ni mo fi dúró de OLUWA,ó dẹ etí sí mi, ó sì gbọ́ igbe mi.

2 Ó fà mí jáde láti inú ọ̀gbun ìparun,láti inú kòtò tí ó kún fún ẹrọ̀fọ̀;ó gbé mi kalẹ̀ lórí àpáta,ó sì fi ẹsẹ̀ mi tẹlẹ̀.

3 Ó fi orin titun sí mi lẹ́nu,àní, orin ìyìn sí Ọlọrun wa.Ọ̀pọ̀ yóo rí i, ẹ̀rù óo bà wọ́n,wọn óo sì gbẹ́kẹ̀lé OLUWA.

4 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà,tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé OLUWA,tí kò bá àwọn onigbeeraga rìn,àwọn tí wọn ti ṣìnà lọ sọ́dọ̀ àwọn oriṣa.

5 OLUWA, Ọlọrun mi, o ti ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu fún wa,o sì ti ro ọ̀pọ̀ èrò rere kàn wá.Kò sí ẹni tí a lè fi wé ọ;bí mo bá ní kí n máa polongo ohun tí o ṣe,kí n máa ròyìn wọn,wọ́n ju ohun tí eniyan lè kà lọ.

6 O ò fẹ́ ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni o ò fẹ́ ọrẹ,ṣugbọn o là mí ní etí;o ò bèèrè ẹbọ sísun tabi ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

7 Nígbà náà ni mo wí pé, “Wò ó, mo dé;a ti kọ nípa mi sinu ìwé pé:

8 mo gbádùn láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọrun mi;mo sì ń pa òfin rẹ mọ́ ninu ọkàn mi.”

9 Mo ti ròyìn òdodo ninu àwùjọ ńlá.Wò ó, OLUWA n kò pa ẹnu mi mọ́,gẹ́gẹ́ bí o ti mọ̀.

10 Èmi kò fi ìròyìn ìrànlọ́wọ́ ìgbàlà rẹ pamọ́.Mo sọ̀rọ̀ òtítọ́ ati ìgbàlà rẹ;n kò dákẹ́ lẹ́nu nípa òtítọ́ ati ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀,ninu àwùjọ ńlá.

11 Má dáwọ́ àánú rẹ dúró lórí mi, OLUWA,sì jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ati òtítọ́ rẹ máa pa mí mọ́.

Adura Ìrànlọ́wọ́

12 Nítorí pé àìmọye ìdààmú ló yí mi ká,ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi ti tẹ̀ mí,tóbẹ́ẹ̀ tí n kò ríran.Wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,ọkàn mi ti dàrú.

13 OLUWA, dákun gbà mi;yára, OLUWA, ràn mí lọ́wọ́.

14 Jẹ́ kí ojú ti gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́gba ẹ̀mí mi,kí ìdàrúdàpọ̀ bá gbogbo wọn patapata,jẹ́ kí á lé àwọn tí ń wá ìpalára mi pada sẹ́yìn,kí wọ́n sì tẹ́.

15 Jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wọ́n,kí wọ́n sì gba èrè ìtìjú,àní, àwọn tí ń ṣe jàgínní mi.

16 Kí gbogbo àwọn tí ń wá ọ máa yọ̀,kí inú wọn sì máa dùn nítorí rẹ;kí àwọn tí ó fẹ́ràn ìgbàlà rẹmáa wí nígbà gbogbo pé, “OLUWA tóbi!”

17 Ní tèmi, olùpọ́njú ati aláìní ni mí;ṣugbọn Oluwa kò gbàgbé mi.Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ ati olùgbàlà mi,má pẹ́, Ọlọrun mi.