1 Ọlọrun, ìwọ ni Ọlọrun mi, mò ń wá ọ,ọkàn rẹ ń fà mí;bí ilẹ̀ tí ó ti ṣá, tí ó sì gbẹṣe máa ń kóǹgbẹ omi.
2 Mo ti ń wò ọ́ ninu ilé mímọ́ rẹ,mo ti rí agbára ati ògo rẹ.
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ dára ju ìyè lọ,n óo máa yìn ọ́.
4 N óo máa yìn ọ́ títí ayé mi;n óo máa tẹ́wọ́ adura sí ọ.
5 Ẹ̀mí mi yóo ní ànító ati àníṣẹ́kù;n óo sì fi ayọ̀ kọ orin ìyìn sí ọ.
6 Nígbà tí mo bá ranti rẹ lórí ibùsùn mi,tí mo bá ń ṣe àṣàrò nípa rẹ ní gbogbo òru;
7 nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ mi,lábẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ ni mò ń fi ayọ̀ kọrin.
8 Ẹ̀mí mi rọ̀ mọ́ ọ;ọwọ́ ọ̀tun rẹ ni ó gbé mi ró.
9 Ṣugbọn àwọn tí ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí miyóo sọ̀kalẹ̀ lọ sinu isà òkú.
10 A ó fi idà pa wọ́n lójú ogun,ẹranko ni yóo sì jẹ òkú wọn.
11 Ṣugbọn ọba yóo máa yọ̀ ninu Ọlọrun;gbogbo àwọn tí ń fi orúkọ OLUWA búrayóo máa fògo fún un;ṣugbọn a ó pa àwọn òpùrọ́ lẹ́nu mọ́.