1 Gbọ́ igbe mi, Ọlọrun,fetí sí adura mi.
2 Láti ọ̀nà jíjìn réré ni mo ti ké pè ọ́,nígbà tí àárẹ̀ mú mi.Tọ́ mi lọ sí ibi àpáta tí ó ga jù mí lọ,
3 nítorí ìwọ ni ààbò mi,ìwọ ni ilé ìṣọ́ tí ó lágbáraláti dáàbò bò mí lọ́wọ́ ọ̀tá.
4 Jẹ́ kí n máa gbé inú àgọ́ rẹ títí lae,kí n lè máa wà láìléwu lábẹ́ ààbò ìyẹ́ rẹ.
5 Nítorí ìwọ, Ọlọrun, ti gbọ́ ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́;o ti fún mi ní ogún tí o pèsè fún àwọn tí ó bẹ̀rù orúkọ rẹ.
6 Jẹ́ kí ẹ̀mí ọba ó gùn;kí ó pẹ́ láyé kánrinkése.
7 Kí ó máa gúnwà níwájú Ọlọrun títí lae;máa fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, ati òtítọ́ rẹ ṣọ́ ọ.
8 Bẹ́ẹ̀ ni n óo máa kọ orin ìyìn orúkọ rẹ títí lae,nígbà tí mo bá ń san ẹ̀jẹ́ mi lojoojumọ.