Orin Dafidi 118 BM

Adura Ọpẹ́ fún Ìṣẹ́gun

1 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.

2 Jẹ́ kí Israẹli wí pé,“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”

3 Kí àwọn ará ilé Aaroni wí pé,“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”

4 Kí àwọn tí ó bẹ̀rù OLUWA wí pé,“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.”

5 Ninu ìpọ́njú, mo ké pe OLUWA,ó dá mi lóhùn, ó sì tú mi sílẹ̀.

6 Nígbà tí OLUWA wà pẹlu mi, ẹ̀rù kò bà mí.Kí ni eniyan lè fi mí ṣe?

7 OLUWA wà pẹlu mi láti ràn mí lọ́wọ́,nítorí náà, n óo wo àwọn tí wọ́n kórìíra mipẹlu ayọ̀ ìṣẹ́gun.

8 Ó sàn láti sá di OLUWA,ju ati gbẹ́kẹ̀lé eniyan lọ.

9 Ó sàn láti sá di OLUWA,ju ati gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìjòyè.

10 Gbogbo orílẹ̀-èdè dòòyì ká mi,ṣugbọn ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run!

11 Wọ́n yí mi ká, àní, wọ́n dòòyì ká mi,ṣugbọn ni orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run!

12 Wọ́n ṣùrù bò mí bí oyin,ṣugbọn kíá ni wọ́n kú bí iná ìṣẹ́pẹ́;ní orúkọ OLUWA, mo pa wọ́n run.

13 Wọ́n gbógun tì mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fẹ́rẹ̀ ṣubú,ṣugbọn OLUWA ràn mí lọ́wọ́.

14 OLUWA ni agbára ati orin mi,ó ti di olùgbàlà mi.

15 Ẹ gbọ́ orin ayọ̀ ìṣẹ́gun,ninu àgọ́ àwọn olódodo.“Ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá.

16 A gbé ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ga,ọwọ́ ọ̀tún OLUWA ti ṣe iṣẹ́ agbára ńlá!”

17 N ò ní kú, yíyè ni n óo yè,n óo sì máa fọnrere nǹkan tí OLUWA ṣe.

18 OLUWA jẹ mí níyà pupọ,ṣugbọn kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.

19 Ṣí ìlẹ̀kùn òdodo fún mi,kí n lè gba ibẹ̀ wọlé,kí n sì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA.

20 Èyí ni ẹnu ọ̀nà OLUWA;àwọn olódodo yóo gba ibẹ̀ wọlé.

21 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, nítorí pé o gbọ́ ohùn mi,o sì ti di olùgbàlà mi.

22 Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,ni ó di pataki igun ilé.

23 OLUWA ló ṣe èyí;ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa.

24 Òní ni ọjọ́ tí OLUWA dá,ẹ jẹ́ kí á máa yọ̀, kí inú wa sì máa dùn.

25 OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, gbà wá,OLUWA, à ń bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí á ṣe àṣeyege.

26 Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ OLUWA,láti inú ilé rẹ ni a ti ń yìn ọ́, OLUWA.

27 OLUWA ni Ọlọrun, ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí wa.Pẹlu ẹ̀ka igi lọ́wọ́, ẹ bẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ ìwọ́de ẹbọ náà,títí dé ibi ìwo pẹpẹ.

28 Ìwọ ni Ọlọrun mi,n óo máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ.Ìwọ ni Ọlọrun mi,n óo máa gbé ọ ga.

29 Ẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ OLUWA, nítorí pé ó ṣeun,nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae.